Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 26:11-22 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Bí ajá tíí pada sídìí èébì rẹ̀bẹ́ẹ̀ ni òmùgọ̀ tó pada sí ìwà agọ̀ rẹ̀.

12. Ìrètí ń bẹ fún òmùgọ̀ju ẹni tí ó gbọ́n lójú ara rẹ̀ lọ.

13. Ọ̀lẹ ń wí pé, “Kinniun kan wà lọ́nà!Kinniun buburu kan wà ní ìgboro!”

14. Bí ìlẹ̀kùn ṣe ń ṣí síhìn-ín, sọ́hùn-ún, lórí ìdè rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ń yí síhìn-ín, sọ́hùn-ún, lórí ibùsùn rẹ̀.

15. Ọ̀lẹ ti ọwọ́ bọ àwo oúnjẹ,ṣugbọn ó lẹ kọjá kí ó lè bu oúnjẹ kí ó fi bọ ẹnu.

16. Ọ̀lẹ gbọ́n lójú ara rẹ̀ju eniyan meje tí wọ́n lè dáhùn ọ̀rọ̀ pẹlu ọgbọ́n lọ.

17. Ẹni tí ó ti ọrùn bọ ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀,dàbí ẹni tí ó gbá ajá alájá létí mú.

18. Bíi aṣiwèrè tí ó ju igi iná tabi ọfà olóró,

19. ni ẹni tó ṣi ẹlòmíràn lọ́nà,tí ó wá ń sọ pé “Mo kàn ń ṣeré ni!”

20. Láìsí igi, iná óo kú,bẹ́ẹ̀ ni, láìsí olófòófó, ìjà óo tán.

21. Bí èédú ti rí sí ògúnná, ati igi sí iná,bẹ́ẹ̀ ni oníjà eniyan rí, sí àtidá ìjà sílẹ̀.

22. Ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ olófòófó dàbí òkèlè oúnjẹ dídùna máa wọni lára ṣinṣin.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 26