Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 25:5-13 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Mú àwọn olùdámọ̀ràn ibi kúrò lọ́dọ̀ ọba,a óo sì fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ pẹlu òdodo.

6. Má ṣe gbéraga níwájú ọba,tabi kí o jókòó ní ipò àwọn eniyan pataki,

7. nítorí ó sàn kí ó wí fún ọ pé,“Máa bọ̀ lókè níhìn-ín”,jù pé kí ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ níwájú ọlọ́lá kan lọ.

8. Má fi ìwàǹwára fa ẹnikẹ́ni lọ sílé ẹjọ́,nítorí kí ni o óo ṣe nígbà tí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́.

9. Bí o bá ń bá aládùúgbò rẹ ṣe àríyànjiyànmá ṣe tú àṣírí ẹlòmíràn,

10. kí ẹni tí ó bá gbọ́ má baà dójútì ọ́,kí o má baà sọ ara rẹ lórúkọ.

11. Ọ̀rọ̀ tí a sọ lákòókò tí ó yẹdàbí ohun ọ̀ṣọ́ wúrà tí a gbé sinu àwo fadaka.

12. Ìbáwí ọlọ́gbọ́n dàbí òrùka wúrà,tabi ohun ọ̀ṣọ́ tí a fi wúrà ṣe,fún ẹni tí ó ní etí láti fi gbọ́.

13. Bí òtútù yìnyín nígbà ìkórè,bẹ́ẹ̀ ni olóòótọ́ iranṣẹ jẹ́, sí àwọn tí ó rán an,a máa fi ọkàn àwọn oluwa rẹ̀ balẹ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 25