Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 25:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn òwe mìíràn tí Solomoni pa,tí àwọn òṣìṣẹ́ Hesekaya ọba Juda kọ sílẹ̀ nìwọ̀nyí.

2. Ògo ni ó jẹ́ fún Ọlọrun láti fi nǹkan pamọ́,ṣugbọn ògo ló sá tún jẹ́ fún ọbaláti wádìí nǹkan ní àwárí.

3. Bí ọ̀run ti ga, tí ilẹ̀ sì jìn,bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò lè mọ ohun tí ó wà lọ́kàn àwọn ọba.

4. Yọ́ gbogbo ìdọ̀tí tí ó wà lára fadaka kúrò,alágbẹ̀dẹ yóo sì rí fadaka fi ṣe ohun èlò.

5. Mú àwọn olùdámọ̀ràn ibi kúrò lọ́dọ̀ ọba,a óo sì fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ pẹlu òdodo.

6. Má ṣe gbéraga níwájú ọba,tabi kí o jókòó ní ipò àwọn eniyan pataki,

7. nítorí ó sàn kí ó wí fún ọ pé,“Máa bọ̀ lókè níhìn-ín”,jù pé kí ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ níwájú ọlọ́lá kan lọ.

8. Má fi ìwàǹwára fa ẹnikẹ́ni lọ sílé ẹjọ́,nítorí kí ni o óo ṣe nígbà tí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́.

9. Bí o bá ń bá aládùúgbò rẹ ṣe àríyànjiyànmá ṣe tú àṣírí ẹlòmíràn,

10. kí ẹni tí ó bá gbọ́ má baà dójútì ọ́,kí o má baà sọ ara rẹ lórúkọ.

11. Ọ̀rọ̀ tí a sọ lákòókò tí ó yẹdàbí ohun ọ̀ṣọ́ wúrà tí a gbé sinu àwo fadaka.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 25