Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 24:5-15 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ọlọ́gbọ́n lágbára ju akọni lọ,ẹni tí ó ní ìmọ̀ sì ju alágbára lọ.

6. Nítorí nípa ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n, o lè jagun,ọpọlọpọ ìmọ̀ràn níí sìí mú ìṣẹ́gun wà.

7. Ọgbọ́n ga jù fún òmùgọ̀,kì í lè lanu sọ̀rọ̀ láwùjọ.

8. Ẹni tí ń pète àtiṣe ibini a óo máa pè ní oníṣẹ́ ibi.

9. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ète òmùgọ̀,ẹni ìríra sì ni pẹ̀gànpẹ̀gàn.

10. Bí o bá kùnà lọ́jọ́ ìpọ́njú,a jẹ́ pé agbára rẹ kò tó.

11. Gba àwọn tí wọ́n bá fẹ́ lọ pa sílẹ̀,fa àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n,lọ sọ́dọ̀ àwọn apànìyàn pada.

12. Bí ẹ bá sọ pé ẹ kò mọ nǹkan nípa rẹ̀,ṣé ẹni tí ó mọ èrò ọkàn kò rí i?Ṣé ẹni tí ń pa ẹ̀mí rẹ mọ́ kò mọ̀,àbí kò ní san án fún eniyangẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀?

13. Ọmọ mi, jẹ oyin, nítorí pé ó dùn,oyin tí a fún láti inú afárá a sì máa dùn lẹ́nu.

14. Mọ̀ dájú pé bẹ́ẹ̀ ni ọgbọ́n yóo rí fún ọ,bí o bá ní i, yóo dára fún ọ lẹ́yìn ọ̀la,ìrètí rẹ kò sì ní di asán.

15. Má lúgọ bí eniyan burúkú láti kó ilé olódodo,má fọ́ ilé rẹ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 24