5. Ọlọ́gbọ́n lágbára ju akọni lọ,ẹni tí ó ní ìmọ̀ sì ju alágbára lọ.
6. Nítorí nípa ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n, o lè jagun,ọpọlọpọ ìmọ̀ràn níí sìí mú ìṣẹ́gun wà.
7. Ọgbọ́n ga jù fún òmùgọ̀,kì í lè lanu sọ̀rọ̀ láwùjọ.
8. Ẹni tí ń pète àtiṣe ibini a óo máa pè ní oníṣẹ́ ibi.
9. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ète òmùgọ̀,ẹni ìríra sì ni pẹ̀gànpẹ̀gàn.
10. Bí o bá kùnà lọ́jọ́ ìpọ́njú,a jẹ́ pé agbára rẹ kò tó.
11. Gba àwọn tí wọ́n bá fẹ́ lọ pa sílẹ̀,fa àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n,lọ sọ́dọ̀ àwọn apànìyàn pada.
12. Bí ẹ bá sọ pé ẹ kò mọ nǹkan nípa rẹ̀,ṣé ẹni tí ó mọ èrò ọkàn kò rí i?Ṣé ẹni tí ń pa ẹ̀mí rẹ mọ́ kò mọ̀,àbí kò ní san án fún eniyangẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀?
13. Ọmọ mi, jẹ oyin, nítorí pé ó dùn,oyin tí a fún láti inú afárá a sì máa dùn lẹ́nu.