Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 24:3-11 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ọgbọ́n ni a fi ń kọ́lé,òye ni a fi ń fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.

4. Pẹlu ìmọ̀ ni eniyan fi í kóoniruuru nǹkan ìní dáradáraolówó iyebíyekún àwọn yàrá rẹ̀

5. Ọlọ́gbọ́n lágbára ju akọni lọ,ẹni tí ó ní ìmọ̀ sì ju alágbára lọ.

6. Nítorí nípa ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n, o lè jagun,ọpọlọpọ ìmọ̀ràn níí sìí mú ìṣẹ́gun wà.

7. Ọgbọ́n ga jù fún òmùgọ̀,kì í lè lanu sọ̀rọ̀ láwùjọ.

8. Ẹni tí ń pète àtiṣe ibini a óo máa pè ní oníṣẹ́ ibi.

9. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ète òmùgọ̀,ẹni ìríra sì ni pẹ̀gànpẹ̀gàn.

10. Bí o bá kùnà lọ́jọ́ ìpọ́njú,a jẹ́ pé agbára rẹ kò tó.

11. Gba àwọn tí wọ́n bá fẹ́ lọ pa sílẹ̀,fa àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n,lọ sọ́dọ̀ àwọn apànìyàn pada.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 24