Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 24:17-34 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Má yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú,má sì jẹ́ kí inú rẹ dùn bí ó bá kọsẹ̀,

18. kí OLUWA má baà bínú sí ọ tí ó bá rí ọ,kí ó sì yí ojú ibinu rẹ̀ pada kúrò lára ọ̀tá rẹ.

19. Má ṣe kanra nítorí àwọn aṣebi,má sì ṣe jowú eniyan burúkú,

20. nítorí pé kò sí ìrètí fún ẹni ibi,a óo sì pa àtùpà eniyan burúkú.

21. Ọmọ mi, bẹ̀rù OLUWA ati ọba,má ṣe àìgbọràn sí ọ̀kankan ninu wọn;

22. nítorí jamba lè ti ọ̀dọ̀ wọn wá lójijì,ta ló mọ irú ìparun, tí ó lè ti ọ̀dọ̀ àwọn mejeeji wá?

23. Àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tún nìwọ̀nyí:Kò dára láti máa ṣe ojuṣaaju ninu ìdájọ́.

24. Ẹni tí ó sọ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ pé ọwọ́ rẹ̀ mọ́,àwọn eniyan yóo gbé e ṣépè,àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì kórìíra rẹ̀.

25. Ṣugbọn yóo dára fún àwọn tí wọ́n bá dá ẹ̀bi fún ẹni tí ó jẹ̀bi,ibukun Ọlọrun yóo sì bá wọn.

26. Ẹni tí ó bá fèsì tí ó tọ́dàbí ẹni tí ó fi ẹnu koni lẹ́nu.

27. Parí iṣẹ́ tí ò ń ṣe níta,tọ́jú gbogbo nǹkan oko rẹ,lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.

28. Má jẹ́rìí lòdì sí aládùúgbò rẹ láìnídìí,má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ti ẹnu rẹ jáde.

29. Má sọ pé, “Bí lágbájá ti ṣe sí mi,bẹ́ẹ̀ ni èmi náà yóo ṣe sí i,n óo san ẹ̀san ohun tí ó ṣe fún un.”

30. Mo gba ẹ̀gbẹ́ oko ọ̀lẹ kan kọjá,mo kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà àjàrà ẹnìkan tí kò lóye.

31. Wò ó! Ẹ̀gún ti hù níbi gbogbo,igbó ti bo gbogbo rẹ̀ mọ́lẹ̀,ọgbà tí ó fi òkúta ṣe yí i ká sì ti wó.

32. Mo ṣe àṣàrò lórí ohun tí mo ṣàkíyèsí,mo sì kọ́ ẹ̀kọ́ lára ohun tí mo rí.

33. Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,ìkáwọ́ gbera díẹ̀ láti sinmi,

34. bẹ́ẹ̀ ni òṣì yóo ṣe dé bá ọbíi kí olè yọ sí eniyan,àìní yóo sì wọlé tọ̀ ọ́ bí ẹni tí ó di ihamọra ogun.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 24