Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 24:15-24 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Má lúgọ bí eniyan burúkú láti kó ilé olódodo,má fọ́ ilé rẹ̀.

16. Nítorí pé bí olódodo bá ṣubú léra léra nígbà meje, yóo tún dìde,ṣugbọn àjálù máa ń bi ẹni ibi ṣubú.

17. Má yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú,má sì jẹ́ kí inú rẹ dùn bí ó bá kọsẹ̀,

18. kí OLUWA má baà bínú sí ọ tí ó bá rí ọ,kí ó sì yí ojú ibinu rẹ̀ pada kúrò lára ọ̀tá rẹ.

19. Má ṣe kanra nítorí àwọn aṣebi,má sì ṣe jowú eniyan burúkú,

20. nítorí pé kò sí ìrètí fún ẹni ibi,a óo sì pa àtùpà eniyan burúkú.

21. Ọmọ mi, bẹ̀rù OLUWA ati ọba,má ṣe àìgbọràn sí ọ̀kankan ninu wọn;

22. nítorí jamba lè ti ọ̀dọ̀ wọn wá lójijì,ta ló mọ irú ìparun, tí ó lè ti ọ̀dọ̀ àwọn mejeeji wá?

23. Àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tún nìwọ̀nyí:Kò dára láti máa ṣe ojuṣaaju ninu ìdájọ́.

24. Ẹni tí ó sọ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ pé ọwọ́ rẹ̀ mọ́,àwọn eniyan yóo gbé e ṣépè,àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì kórìíra rẹ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 24