Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 24:13-26 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Ọmọ mi, jẹ oyin, nítorí pé ó dùn,oyin tí a fún láti inú afárá a sì máa dùn lẹ́nu.

14. Mọ̀ dájú pé bẹ́ẹ̀ ni ọgbọ́n yóo rí fún ọ,bí o bá ní i, yóo dára fún ọ lẹ́yìn ọ̀la,ìrètí rẹ kò sì ní di asán.

15. Má lúgọ bí eniyan burúkú láti kó ilé olódodo,má fọ́ ilé rẹ̀.

16. Nítorí pé bí olódodo bá ṣubú léra léra nígbà meje, yóo tún dìde,ṣugbọn àjálù máa ń bi ẹni ibi ṣubú.

17. Má yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú,má sì jẹ́ kí inú rẹ dùn bí ó bá kọsẹ̀,

18. kí OLUWA má baà bínú sí ọ tí ó bá rí ọ,kí ó sì yí ojú ibinu rẹ̀ pada kúrò lára ọ̀tá rẹ.

19. Má ṣe kanra nítorí àwọn aṣebi,má sì ṣe jowú eniyan burúkú,

20. nítorí pé kò sí ìrètí fún ẹni ibi,a óo sì pa àtùpà eniyan burúkú.

21. Ọmọ mi, bẹ̀rù OLUWA ati ọba,má ṣe àìgbọràn sí ọ̀kankan ninu wọn;

22. nítorí jamba lè ti ọ̀dọ̀ wọn wá lójijì,ta ló mọ irú ìparun, tí ó lè ti ọ̀dọ̀ àwọn mejeeji wá?

23. Àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tún nìwọ̀nyí:Kò dára láti máa ṣe ojuṣaaju ninu ìdájọ́.

24. Ẹni tí ó sọ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ pé ọwọ́ rẹ̀ mọ́,àwọn eniyan yóo gbé e ṣépè,àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì kórìíra rẹ̀.

25. Ṣugbọn yóo dára fún àwọn tí wọ́n bá dá ẹ̀bi fún ẹni tí ó jẹ̀bi,ibukun Ọlọrun yóo sì bá wọn.

26. Ẹni tí ó bá fèsì tí ó tọ́dàbí ẹni tí ó fi ẹnu koni lẹ́nu.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 24