Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 23:29-34 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Ta ló ni òṣì? Ta ló ni ìbànújẹ́?Ta ló ni ìjà? Ta ló ni asọ̀?Ta ló ni ọgbẹ́ láìnídìí? Ta ló ni ojú pípọ́n koko?

30. Àwọn tí wọn máa ń pẹ́ ní ìdí ọtí ni,àwọn tí wọn ń mu ọtí àdàlú.

31. Má jẹ́ kí pípọ́n tí ọtí pọ́n fà ọ́ mọ́ra,nígbà tí ó bá ń ta wínníwínní ninu ife,tí o dà á mu, tí ó lọ geere lọ́nà ọ̀fun.

32. Nígbà tí ó bá yá, á máa buni ṣán bí ejò,oró rẹ̀ á sì dàbí ti ejò paramọ́lẹ̀.

33. Ojú rẹ yóo rí nǹkan àjèjì,ọkàn rẹ á máa ro èròkerò.

34. O óo dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ lórí agbami òkun,bí ẹni tí ó sùn lórí òpó ọkọ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 23