Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 23:25-32 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Mú inú baba ati ìyá rẹ dùn,jẹ́ kí ìyá tí ó bí ọ láyọ̀ lórí rẹ.

26. Ọmọ mi, gbọ́ tèmi,kí o sì máa kíyèsí ọ̀nà mi.

27. Nítorí aṣẹ́wó dàbí ọ̀fìn jíjìn,obinrin onírìnkurìn sì dàbí kànga tí ó jìn.

28. A máa ba níbùba bí olè,a sì máa sọ ọpọlọpọ ọkunrin di alágbèrè.

29. Ta ló ni òṣì? Ta ló ni ìbànújẹ́?Ta ló ni ìjà? Ta ló ni asọ̀?Ta ló ni ọgbẹ́ láìnídìí? Ta ló ni ojú pípọ́n koko?

30. Àwọn tí wọn máa ń pẹ́ ní ìdí ọtí ni,àwọn tí wọn ń mu ọtí àdàlú.

31. Má jẹ́ kí pípọ́n tí ọtí pọ́n fà ọ́ mọ́ra,nígbà tí ó bá ń ta wínníwínní ninu ife,tí o dà á mu, tí ó lọ geere lọ́nà ọ̀fun.

32. Nígbà tí ó bá yá, á máa buni ṣán bí ejò,oró rẹ̀ á sì dàbí ti ejò paramọ́lẹ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 23