Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 23:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí o bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun,kíyèsí ẹni tí ó bá wà níwájú rẹ dáradára.

2. Tí o bá jẹ́ wọ̀bìà eniyan, ṣọ́ra,kí o má fi ọ̀bẹ lé ara rẹ lọ́fun.

3. Má jẹ́ kí oúnjẹ aládìídùn rẹ̀ wọ̀ ọ́ lójú,nítorí ó lè jẹ́ oúnjẹ ẹ̀tàn.

4. Má ṣe làálàá àṣejù láti kó ọrọ̀ jọ,fi ọgbọ́n sẹ́ ara rẹ.

5. Kí o tó ṣẹ́jú pẹ́, owó rẹ lè ti lọ,ó le gúnyẹ̀ẹ́ kí ó fò,bí ìgbà tí ẹyẹ àṣá bá fò lọ.

6. Má ṣe jẹ oúnjẹ ahun,má ní ìfẹ́ sí oúnjẹ aládìídùn rẹ̀;

7. nítorí ẹni tí ó máa fi ọkàn ṣírò owó oúnjẹ ni.Ó lè máa wí fún ọ pé, “Jẹ, kí o sì mu!”ṣugbọn kò dé inú rẹ̀.

8. O óo pọ gbogbo òkèlè tí o jẹ,gbogbo ọ̀rọ̀ dídùn tí o sọ yóo sì jẹ́ àsọdànù.

9. Má sọ̀rọ̀ létí òmùgọ̀,nítorí yóo gan ọgbọ́n tí ó wà ninu ọ̀rọ̀ tí o sọ.

10. Má ṣe hú ohun tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ fi pa ààlà láti ìgbà àtijọ́,má sì gba ilẹ̀ ọmọ aláìníbaba;

11. nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára,yóo gba ìjà wọn jà.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 23