Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 20:5-18 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Èrò ọkàn eniyan dàbí omi jíjìn,ẹni tí ó bá ní ìmọ̀ ló lè fà á jáde.

6. Ọ̀pọ̀ eniyan a máa ka ara wọn kún olóòótọ́,ṣugbọn níbo la ti lè rí ẹyọ ẹnìkan tó jẹ́ olódodo?

7. Olódodo a máa rìn ní ọ̀nà òtítọ́,ibukun ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n tẹ̀lé e.

8. Nígbà tí ọba bá jókòó sórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀,ojú ni yóo fi gbọn àwọn ẹni ibi dànù.

9. Ta ló lè sọ pé ọkàn òun mọ́,ati pé òun mọ́, òun kò ní ẹ̀ṣẹ̀?

10. Ayédèrú òṣùnwọ̀n jẹ́ ohun ìríra lójú OLUWA.

11. Ọmọde pàápàá a máa fi irú eniyan tí òun jẹ́ hàn nípa ìṣe rẹ̀,bí ohun tí ó ṣe dára, tí ó sì tọ̀nà.

12. Ati etí tí ń gbọ́ràn, ati ojú tí ń ríran,OLUWA ló dá ekinni-keji wọn.

13. Má fẹ́ràn oorun àsùnjù, kí o má baà di talaka,lajú, o óo sì ní oúnjẹ ní àníṣẹ́kù.

14. “Èyí kò dára, kò dára” ni ẹni tí ń rajà máa ń wí,bí ó bá lọ tán, a máa fọ́nnu ọjà ọ̀pọ̀ tí ó rà.

15. Wúrà ń bẹ, òkúta olówó iyebíye sì wà lọpọlọpọ,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ni ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye.

16. Gba ẹ̀wù ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò,gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onígbọ̀wọ́ ẹni tí kò mọ̀ rí.

17. Oúnjẹ tí a bá rí lọ́nà èrú máa ń dùn lẹ́nu eniyan,ṣugbọn nígbà tí a bá jẹ ẹ́ tán, ẹnu ẹni a máa kan.

18. Ìmọ̀ràn níí fìdí ètò múlẹ̀,gba ìtọ́sọ́nà kí o tó lọ jagun.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 20