Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 20:22-30 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Má sọ pé o fẹ́ fi burúkú san burúkú,gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, yóo sì gbà ọ́.

23. Ayédèrú òṣùnwọ̀n jẹ́ ohun ìríra lójú OLUWA,ìwọ̀n èké kò dára.

24. OLUWA ní ń tọ́ ìṣísẹ̀ ẹni,eniyan kò lè ní òye ọ̀nà ara rẹ̀.

25. Ronú jinlẹ̀ kí o tó jẹ́jẹ̀ẹ́ fún OLUWA,kí o má baà kábàámọ̀ rẹ̀.

26. Ọba tó gbọ́n a máa fẹ́ eniyan burúkú dànù,a sì lọ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.

27. Ẹ̀mí eniyan ni fìtílà OLUWA,tíí máa wá gbogbo kọ́lọ́fín inú rẹ̀ kiri.

28. Ìfẹ́ ati òtítọ́ níí mú kí ọba pẹ́,òdodo níí sì ń gbé ìjọba rẹ̀ ró.

29. Agbára ni ògo ọ̀dọ́,ewú sì ni ẹwà àgbà.

30. Ìjìyà tó fa ọgbẹ́ a máa mú ibi kúrò,pàṣán a máa mú kí inú mọ́.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 20