Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 20:12-18 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Ati etí tí ń gbọ́ràn, ati ojú tí ń ríran,OLUWA ló dá ekinni-keji wọn.

13. Má fẹ́ràn oorun àsùnjù, kí o má baà di talaka,lajú, o óo sì ní oúnjẹ ní àníṣẹ́kù.

14. “Èyí kò dára, kò dára” ni ẹni tí ń rajà máa ń wí,bí ó bá lọ tán, a máa fọ́nnu ọjà ọ̀pọ̀ tí ó rà.

15. Wúrà ń bẹ, òkúta olówó iyebíye sì wà lọpọlọpọ,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ni ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye.

16. Gba ẹ̀wù ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò,gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onígbọ̀wọ́ ẹni tí kò mọ̀ rí.

17. Oúnjẹ tí a bá rí lọ́nà èrú máa ń dùn lẹ́nu eniyan,ṣugbọn nígbà tí a bá jẹ ẹ́ tán, ẹnu ẹni a máa kan.

18. Ìmọ̀ràn níí fìdí ètò múlẹ̀,gba ìtọ́sọ́nà kí o tó lọ jagun.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 20