Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 20:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹlẹ́yà ni ọtí waini,aláriwo ní ọtí líle,ẹnikẹ́ni tí a bá fi tànjẹ kò gbọ́n.

2. Ibinu ọba dàbí bíbú kinniun,ẹni tí ó bá mú ọba bínú fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu.

3. Nǹkan iyì ni pé kí eniyan máa yẹra fún ìjà,ṣugbọn òmùgọ̀ eniyan níí máa ń jà.

4. Ọ̀lẹ kì í dáko ní àkókò,nítorí náà, nígbà ìkórè, kò ní rí nǹkankan kó jọ.

5. Èrò ọkàn eniyan dàbí omi jíjìn,ẹni tí ó bá ní ìmọ̀ ló lè fà á jáde.

6. Ọ̀pọ̀ eniyan a máa ka ara wọn kún olóòótọ́,ṣugbọn níbo la ti lè rí ẹyọ ẹnìkan tó jẹ́ olódodo?

7. Olódodo a máa rìn ní ọ̀nà òtítọ́,ibukun ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n tẹ̀lé e.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 20