Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 2:8-20 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ó ń tọ́ wọn sí ìdájọ́ òtítọ́,ó sì ń pa ọ̀nà àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀ mọ́.

9. Nígbà náà ni ìtumọ̀ òdodo ati ẹ̀tọ́ yóo yé ọati àìṣe ojuṣaaju, ati gbogbo ọ̀nà rere.

10. Nítorí ọgbọ́n yóo wọnú ọkàn rẹ,ìmọ̀ yóo sì tu ẹ̀mí rẹ lára,

11. ọgbọ́n inú yóo máa ṣọ́ ọ,òye yóo sì máa dáàbò bò ọ́,

12. yóo máa gbà ọ́ lọ́wọ́ ibi ṣíṣe,ati lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn,

13. àwọn tí wọ́n ti kọ ọ̀nà òdodo sílẹ̀tí wọn sì ń rìn ninu òkùnkùn;

14. àwọn tí wọn ń yọ̀ ninu ìwà ibití wọ́n sì ní inú dídùn sí ìyapa ibi;

15. àwọn tí ọ̀nà wọn wọ́,tí wọ́n kún fún ìwà àrékérekè.

16. A óo gbà ọ́ lọ́wọ́ obinrin oníṣekúṣe,àní lọ́wọ́ obinrin onírìnkurìn pẹlu ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn rẹ̀.

17. Ẹni tí ó kọ ọkọ àárọ̀ rẹ̀ sílẹ̀,tí ó sì gbàgbé majẹmu Ọlọrun rẹ̀.

18. Ẹni tí ilé rẹ̀ rì sinu ìparun,tí ọ̀nà rẹ̀ sì wà ninu ọ̀fìn isà òkú.

19. Kò sí ẹni tí ó tọ̀ ọ́ lọ, tí ó pada rí,bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í tún pada sí ọ̀nà ìyè.

20. Nítorí náà, máa rìn ní ọ̀nà àwọn eniyan rere,sì máa bá àwọn olódodo rìn.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 2