Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 2:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọmọ mi, bí o bá gba ọ̀rọ̀ mi,tí o sì pa òfin mi mọ́,

2. tí o bá ń tẹ́tí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n,tí o sì fi ọkàn sí òye,

3. bí o bá kígbe tí o tọrọ òye tí ó jinlẹ̀,tí o gbóhùn sókè tí o bèèrè ìmọ̀,

4. bí o bá wá ọgbọ́n bí ẹni ń wá fadaka,tí o sì wá a bí ẹni ń wá ìṣúra tí a pamọ́,

5. nígbà náà ni ìbẹ̀rù OLUWA yóo yé ọ.O óo sì rí ìmọ̀ Ọlọrun.

6. Nítorí OLUWA níí fún ni ní ọgbọ́n,ẹnu rẹ̀ sì ni òye ati ìmọ̀ ti ń wá.

7. Ó fún àwọn tí wọn dúró ṣinṣin ní ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n,òun ni ààbò fún àwọn tí wọ́n ń rin ọ̀nà ẹ̀tọ́.

8. Ó ń tọ́ wọn sí ìdájọ́ òtítọ́,ó sì ń pa ọ̀nà àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀ mọ́.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 2