1. Ọmọ mi, bí o bá gba ọ̀rọ̀ mi,tí o sì pa òfin mi mọ́,
2. tí o bá ń tẹ́tí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n,tí o sì fi ọkàn sí òye,
3. bí o bá kígbe tí o tọrọ òye tí ó jinlẹ̀,tí o gbóhùn sókè tí o bèèrè ìmọ̀,
4. bí o bá wá ọgbọ́n bí ẹni ń wá fadaka,tí o sì wá a bí ẹni ń wá ìṣúra tí a pamọ́,
5. nígbà náà ni ìbẹ̀rù OLUWA yóo yé ọ.O óo sì rí ìmọ̀ Ọlọrun.
6. Nítorí OLUWA níí fún ni ní ọgbọ́n,ẹnu rẹ̀ sì ni òye ati ìmọ̀ ti ń wá.