Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 19:10-21 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ìgbádùn kò yẹ òmùgọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ kí ẹrú jọba lórí àwọn ìjòyè.

11. Ọgbọ́n kì í jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yára bínú,ògo rẹ̀ sì níláti fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ dá.

12. Ibinu ọba dàbí bíbú kinniun,ṣugbọn ojurere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko tútù.

13. Òmùgọ̀ ọmọ lè kó ìparun bá baba rẹ̀,iyawo oníjà dàbí omi òjò tí ń kán tó, tó, tó, láì dáwọ́ dúró.

14. A máa ń jogún ilé ati ọrọ̀ lọ́wọ́ baba ẹni,ṣugbọn OLUWA níí fúnni ní aya rere.

15. Ìwà ọ̀lẹ a máa múni sùn fọnfọn,ebi níí sìí pa alápá-má-ṣiṣẹ́.

16. Ẹni tí ó bá pa òfin mọ́, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó pamọ́,ẹni tí ó kọ ọ̀nà Ọlọrun sílẹ̀ yóo kú.

17. Ẹni tí ó ṣe ojurere fún àwọn talaka, OLUWA ni ó ṣe é fún,OLUWA yóo sì san ẹ̀san rẹ̀ fún un.

18. Bá ọmọ rẹ wí nígbà tí ó sì lè gbọ́ ìbáwí,má sì ṣe wá ìparun rẹ̀.

19. Onínúfùfù yóo jìyà inúfùfù rẹ̀,bí o bá gbà á sílẹ̀ lónìí, o níláti tún gbà á sílẹ̀ lọ́la.

20. Gbọ́ ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́,kí o lè rí ọgbọ́n lò lẹ́yìn ọ̀la.

21. Ọpọlọpọ ni èrò tí ó wà lọ́kàn ọmọ eniyan,ṣugbọn ìfẹ́ OLUWA ni àṣẹ.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 19