Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 19:1-14 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Talaka tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inú,ó sàn ju òmùgọ̀ eniyan, tí ó ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn lọ.

2. Kò dára kí eniyan wà láìní ìmọ̀,ẹni bá ń kánjú rìn jù a máa ṣìnà.

3. Nígbà tí ìwà òmùgọ̀ bá kó ìparun bá a,ọkàn rẹ̀ a máa bá OLUWA bínú.

4. Ọrọ̀ a máa mú kí eniyan ní ọpọlọpọ ọ̀rẹ́ titun,ṣugbọn àwọn ọ̀rẹ́ talaka a máa kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

5. Ẹlẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,bẹ́ẹ̀ ni òpùrọ́ kò ní bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀san ibi.

6. Ọ̀pọ̀ eniyan níí máa ń wá ojurere ẹni tó lawọ́,gbogbo eniyan sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ń fúnni lẹ́bùn.

7. Gbogbo àwọn arakunrin talaka ni wọ́n kórìíra rẹ̀,kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jìnnà sí i!Ó fọ̀rọ̀ ẹnu fà wọ́n títí, sibẹ wọn kò súnmọ́ ọn.

8. Ẹni tí ó ní ọgbọ́n fẹ́ràn ara rẹ̀,ẹni tí ó bá sì ní òye, yóo ṣe rere.

9. Ẹlẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,ẹni tí ó ń pa irọ́ yóo parun.

10. Ìgbádùn kò yẹ òmùgọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ kí ẹrú jọba lórí àwọn ìjòyè.

11. Ọgbọ́n kì í jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yára bínú,ògo rẹ̀ sì níláti fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ dá.

12. Ibinu ọba dàbí bíbú kinniun,ṣugbọn ojurere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko tútù.

13. Òmùgọ̀ ọmọ lè kó ìparun bá baba rẹ̀,iyawo oníjà dàbí omi òjò tí ń kán tó, tó, tó, láì dáwọ́ dúró.

14. A máa ń jogún ilé ati ọrọ̀ lọ́wọ́ baba ẹni,ṣugbọn OLUWA níí fúnni ní aya rere.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 19