Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 18:5-15 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Kò dára kí á ṣe ojuṣaaju sí eniyan burúkú,tabi kí á dá olódodo ní ẹjọ́ ẹ̀bi.

6. Ẹnu òmùgọ̀ a máa dá ìjà sílẹ̀,ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ a sì máa bá a wá pàṣán.

7. Ẹnu òmùgọ̀ ni yóo tì í sinu ìparun,ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ni yóo sì ṣe tàkúté mú un.

8. Ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ olófòófó dàbí òkèlè oúnjẹ dídùn,a máa wọni lára ṣinṣin.

9. Ẹni tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀,ẹgbẹ́ ni òun ati ẹni tí ń ba nǹkan jẹ́.

10. Orúkọ OLUWA jẹ́ ilé-ìṣọ́ tí ó lágbára,olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì yè.

11. Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ìlú olódi wọn,lójú wọn, ó dàbí odi ńlá tí ń dáàbò bò wọ́n.

12. Ìgbéraga níí ṣáájú ìparun,ìrẹ̀lẹ̀ níí ṣáájú iyì.

13. Ìwà òmùgọ̀ ni, ìtìjú sì ni, kí eniyan fèsì sí ọ̀rọ̀ kí ó tó gbọ́ ìdí rẹ̀.

14. Eniyan lè farada àìsàn,ṣugbọn ta ló lè farada ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn?

15. Ọkàn ọlọ́gbọ́n a máa fẹ́ ìmọ̀,etí ni ọlọ́gbọ́n fi wá a kiri.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 18