11. Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ìlú olódi wọn,lójú wọn, ó dàbí odi ńlá tí ń dáàbò bò wọ́n.
12. Ìgbéraga níí ṣáájú ìparun,ìrẹ̀lẹ̀ níí ṣáájú iyì.
13. Ìwà òmùgọ̀ ni, ìtìjú sì ni, kí eniyan fèsì sí ọ̀rọ̀ kí ó tó gbọ́ ìdí rẹ̀.
14. Eniyan lè farada àìsàn,ṣugbọn ta ló lè farada ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn?
15. Ọkàn ọlọ́gbọ́n a máa fẹ́ ìmọ̀,etí ni ọlọ́gbọ́n fi wá a kiri.
16. Ẹ̀bùn a máa ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ẹni tí ń fúnni lẹ́bùn,a sì mú un dé iwájú ẹni gíga.
17. Ẹni tí ó bá kọ́kọ́ rojọ́ níí dàbí ẹni tí ó jàre,títí tí ẹnìkejì yóo fi bi í ní ìbéèrè,
18. Gègé ṣíṣẹ́ a máa yanjú ọ̀rọ̀a sì parí gbolohun asọ̀ láàrin àwọn alágbára.