Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 18:1-14 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Onímọ-tara-ẹni-nìkan ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀,láti tako ìdájọ́ òtítọ́.

2. Òmùgọ̀ kò ní inú dídùn sí ìmọ̀,àfi kí ó ṣá máa sọ èrò ọkàn rẹ̀.

3. Nígbà tí ìwà burúkú bá dé, ẹ̀gàn yóo dé,bí àbùkù bá wọlé ìtìjú yóo tẹ̀lé e.

4. Ọ̀rọ̀ ẹnu eniyan dàbí odò jíjìn,orísun ọgbọ́n dàbí omi odò tí ń tú jáde.

5. Kò dára kí á ṣe ojuṣaaju sí eniyan burúkú,tabi kí á dá olódodo ní ẹjọ́ ẹ̀bi.

6. Ẹnu òmùgọ̀ a máa dá ìjà sílẹ̀,ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ a sì máa bá a wá pàṣán.

7. Ẹnu òmùgọ̀ ni yóo tì í sinu ìparun,ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ni yóo sì ṣe tàkúté mú un.

8. Ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ olófòófó dàbí òkèlè oúnjẹ dídùn,a máa wọni lára ṣinṣin.

9. Ẹni tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀,ẹgbẹ́ ni òun ati ẹni tí ń ba nǹkan jẹ́.

10. Orúkọ OLUWA jẹ́ ilé-ìṣọ́ tí ó lágbára,olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì yè.

11. Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ìlú olódi wọn,lójú wọn, ó dàbí odi ńlá tí ń dáàbò bò wọ́n.

12. Ìgbéraga níí ṣáájú ìparun,ìrẹ̀lẹ̀ níí ṣáájú iyì.

13. Ìwà òmùgọ̀ ni, ìtìjú sì ni, kí eniyan fèsì sí ọ̀rọ̀ kí ó tó gbọ́ ìdí rẹ̀.

14. Eniyan lè farada àìsàn,ṣugbọn ta ló lè farada ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn?

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 18