Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 17:7-18 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ọ̀rọ̀ rere ṣe àjèjì sí ẹnu òmùgọ̀,bẹ́ẹ̀ ni irọ́ pípa kò yẹ àwọn olórí.

8. Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ dàbí òògùn ajẹ́-bí-idán lójú ẹni tí ń fúnni,ibi gbogbo tí olúwarẹ̀ bá lọ ni ó ti ń ṣe àṣeyege.

9. Ẹni tí ń dárí ji ni ń wá ìfẹ́,ẹni tí ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ a máa ya ọ̀rẹ́ nípá.

10. Ìbáwí a máa dun ọlọ́gbọ́nju kí wọ́n nà òmùgọ̀ ní ọgọrun-un pàṣán lọ.

11. Ọ̀tẹ̀ ṣá ni ti eniyan burúkú ní gbogbo ìgbà,ìkà òjíṣẹ́ ni a óo sì rán sí i.

12. Ó sàn kí eniyan pàdé ẹranko beari tí a kó lọ́mọ,ju kí ó pàdé òmùgọ̀ ninu agọ̀ rẹ̀ lọ.

13. Ẹni tí ó fibi san oore,ibi kò ní kúrò ninu ilé rẹ̀ lae.

14. Ìbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí kí eniyan ya odò tí wọn sé,dá a dúró kí ó tó di ńlá.

15. Ẹni tí ń gbé àre fún ẹlẹ́biati ẹni tí ń gbé ẹ̀bi fún aláre,OLUWA kórìíra ekinni-keji wọn.

16. Owó kò wúlò lọ́wọ́ òmùgọ̀ pé kí ó fi ra ọgbọ́n,nígbà tí kò ní òye?

17. Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo,ṣugbọn a bí arakunrin láti dúró tini ní ìgbà ìpọ́njú.

18. Ẹni tí kò bá gbọ́n níí jẹ́jẹ̀ẹ́,láti ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 17