Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 17:22-28 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Ọ̀yàyà jẹ́ òògùn tí ó dára fún ara,ṣugbọn ìbànújẹ́ a máa mú kí eniyan rù.

23. Eniyan burúkú a máa gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ níkọ̀kọ̀,láti yí ìdájọ́ po.

24. Ẹni tí ó ní òye a máa tẹjúmọ́ ọgbọ́n,ṣugbọn ojú òmùgọ̀ kò gbé ibìkan,ó ń wo òpin ilẹ̀ ayé.

25. Òmùgọ̀ ọmọ jẹ́ ìbànújẹ́ baba rẹ̀,ati ọgbẹ́ ọkàn fún ìyá tí ó bí i.

26. Kò tọ̀nà láti fi ipá mú aláìṣẹ̀ san owó ìtanràn,nǹkan burúkú ni kí á na gbajúmọ̀ tí kò rú òfin.

27. Ẹni tí ó bá ní ìmọ̀ a máa kó ahọ́n rẹ̀ ní ìjánu,ẹni tí ó bá jẹ́ olóye eniyan a máa ṣe jẹ́ẹ́.

28. A máa ka òmùgọ̀ pàápàá kún ọlọ́gbọ́n,bí ó bá pa ẹnu rẹ̀ mọ́,olóye ni àwọn eniyan yóo pè é,bí ó bá panu mọ́ tí kò sọ̀rọ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 17