Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 17:15-26 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ẹni tí ń gbé àre fún ẹlẹ́biati ẹni tí ń gbé ẹ̀bi fún aláre,OLUWA kórìíra ekinni-keji wọn.

16. Owó kò wúlò lọ́wọ́ òmùgọ̀ pé kí ó fi ra ọgbọ́n,nígbà tí kò ní òye?

17. Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo,ṣugbọn a bí arakunrin láti dúró tini ní ìgbà ìpọ́njú.

18. Ẹni tí kò bá gbọ́n níí jẹ́jẹ̀ẹ́,láti ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀.

19. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀,ẹni tí ó bá fẹ́ràn kí á máa fi owó ṣe àṣehàn ń wá ìparun.

20. Ẹni tí ó ní ọkàn ẹ̀tàn kò ní ṣe àṣeyege,ẹlẹ́nu meji yóo bọ́ sinu ìyọnu.

21. Ìbànújẹ́ ni kí eniyan bí ọmọ tí kò gbọ́n,kò sí ayọ̀ fún baba òmùgọ̀.

22. Ọ̀yàyà jẹ́ òògùn tí ó dára fún ara,ṣugbọn ìbànújẹ́ a máa mú kí eniyan rù.

23. Eniyan burúkú a máa gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ níkọ̀kọ̀,láti yí ìdájọ́ po.

24. Ẹni tí ó ní òye a máa tẹjúmọ́ ọgbọ́n,ṣugbọn ojú òmùgọ̀ kò gbé ibìkan,ó ń wo òpin ilẹ̀ ayé.

25. Òmùgọ̀ ọmọ jẹ́ ìbànújẹ́ baba rẹ̀,ati ọgbẹ́ ọkàn fún ìyá tí ó bí i.

26. Kò tọ̀nà láti fi ipá mú aláìṣẹ̀ san owó ìtanràn,nǹkan burúkú ni kí á na gbajúmọ̀ tí kò rú òfin.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 17