Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 17:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Kí á fi alaafia jẹun, láìsí ọbẹ̀,ó sàn ju kí á máa fi ẹran jẹun pẹlu ìyọnu lọ.

2. Ẹrú tí ó bá mọ ìwà hù, yóo di ọ̀gá lórí ọmọ tí ń hùwà ìbàjẹ́,yóo sì jókòó pín ninu ogún bí ẹni pé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ni.

3. Iná ni a fi ń dán fadaka ati wúrà wò,ṣugbọn OLUWA ní ń dán ọkàn wò.

4. Aṣebi a máa tẹ́tí sí ẹni ibi,òpùrọ́ a sì máa fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ìkà.

5. Ẹni tí ń fi talaka ṣẹ̀sín, ẹlẹ́dàá talaka ní ń tàbùkù,ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí wahala ẹni ẹlẹ́ni kò ní lọ láìjìyà.

6. Ọmọ ọmọ ni adé arúgbó,òbí sì ni ògo àwọn ọmọ.

7. Ọ̀rọ̀ rere ṣe àjèjì sí ẹnu òmùgọ̀,bẹ́ẹ̀ ni irọ́ pípa kò yẹ àwọn olórí.

8. Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ dàbí òògùn ajẹ́-bí-idán lójú ẹni tí ń fúnni,ibi gbogbo tí olúwarẹ̀ bá lọ ni ó ti ń ṣe àṣeyege.

9. Ẹni tí ń dárí ji ni ń wá ìfẹ́,ẹni tí ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ a máa ya ọ̀rẹ́ nípá.

10. Ìbáwí a máa dun ọlọ́gbọ́nju kí wọ́n nà òmùgọ̀ ní ọgọrun-un pàṣán lọ.

11. Ọ̀tẹ̀ ṣá ni ti eniyan burúkú ní gbogbo ìgbà,ìkà òjíṣẹ́ ni a óo sì rán sí i.

12. Ó sàn kí eniyan pàdé ẹranko beari tí a kó lọ́mọ,ju kí ó pàdé òmùgọ̀ ninu agọ̀ rẹ̀ lọ.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 17