6. Àánú ati òtítọ́ a máa ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀,ìbẹ̀rù OLUWA a sì máa mú ibi kúrò.
7. Bí ọ̀nà eniyan bá tẹ́ OLUWA lọ́rùn,a máa mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá bá a gbé pẹlu alaafia.
8. Ìwọ̀nba ọrọ̀ pẹlu òdodo,sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ tí a kójọ lọ́nà èrú lọ.
9. Eniyan lè jókòó kí ó ṣètò ìgbésẹ̀ rẹ̀,ṣugbọn OLUWA níí tọ́ ìṣísẹ̀ ẹni.
10. Pẹlu ìmísí Ọlọrun ni ọba fi ń sọ̀rọ̀,ìdájọ́ aiṣododo kò gbọdọ̀ ti ẹnu rẹ̀ jáde.
11. Ti OLUWA ni òṣùnwọ̀n pípé,iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo ohun tí à ń wọ̀n.
12. Àwọn ọba kórìíra ibi ṣíṣe,nítorí nípa òdodo ni a fìdí ìjọba múlẹ̀.
13. Inú ọba a máa dùn sí olódodo,ọba sì máa ń fẹ́ràn àwọn tí ń sọ òtítọ́.
14. Iranṣẹ ikú ni ibinu ọba,ọlọ́gbọ́n eniyan níí tù ú lójú.
15. Ìyè wà ninu ojurere ọba,ojurere rẹ̀ sì dàbí ṣíṣú òjò ní àkókò òjò àkọ́rọ̀.
16. Ó sàn kí eniyan ní òye ju kí ó ní wúrà lọ,ó sì sàn kí eniyan yan ìmọ̀ ju kí ó yan fadaka lọ.
17. Olóòótọ́ kì í tọ ọ̀nà ibi,ẹni tí ń ṣọ́ra, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó ń pamọ́.
18. Ìgbéraga ní ń ṣáájú ìparun,agídí ní ń ṣáájú ìṣubú.
19. Ó sàn kí eniyan jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ pẹlu àwọn talakaju kí ó bá agbéraga pín ìkógun lọ.