Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 16:26-33 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Ebi níí mú kí òṣìṣẹ́ múra síṣẹ́,ohun tí a óo jẹ ní ń lé ni kiri.

27. Eniyan lásán a máa pète ibi,ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dàbí iná tí ń jóni.

28. Ṣòkèṣodò a máa dá ìjà sílẹ̀,ọ̀rọ̀ àhesọ a máa tú ọ̀rẹ́ kòríkòsùn.

29. Ìkà eniyan tan aládùúgbò rẹ̀,ó darí rẹ̀ lọ sọ́nà tí kò tọ́.

30. Ẹni tí ó bá ń ṣẹ́jú sí ni, ète ibi ló fẹ́ pa,ẹni tí ó bá ń fúnnu pọ̀ sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ burúkú ni yóo sọ jáde.

31. Adé ògo ni ewú orí,nípa ìgbé ayé òdodo ni a fi lè ní i.

32. Ẹni tí kì í tètè bínú sàn ju alágbára lọ,ẹni tí ń kó ara rẹ̀ níjàánu sàn ju ẹni tí ó jagun gba odidi ìlú lọ.

33. À máa ṣẹ́ gègé kí á lè mọ ìdí ọ̀ràn,ṣugbọn OLUWA nìkan ló lè pinnu ohunkohun.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 16