1. Èrò ọkàn ni ti eniyanṣugbọn OLUWA ló ni ìdáhùn.
2. Gbogbo ọ̀nà eniyan ni ó mọ́ lójú ara rẹ̀,ṣugbọn OLUWA ló rí ọkàn.
3. Fi gbogbo àdáwọ́lé rẹ lé OLUWA lọ́wọ́,èrò ọkàn rẹ yóo sì yọrí sí rere.
4. OLUWA a máa jẹ́ kí ohun gbogbo yọrí sí bí ó bá ti fẹ́,ó dá eniyan burúkú fún ọjọ́ ìyọnu.
5. OLUWA kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ agbéraga,dájúdájú kò ní lọ láìjìyà.
6. Àánú ati òtítọ́ a máa ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀,ìbẹ̀rù OLUWA a sì máa mú ibi kúrò.
7. Bí ọ̀nà eniyan bá tẹ́ OLUWA lọ́rùn,a máa mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá bá a gbé pẹlu alaafia.
8. Ìwọ̀nba ọrọ̀ pẹlu òdodo,sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ tí a kójọ lọ́nà èrú lọ.