Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 14:14-27 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Alágàbàgebè yóo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́,ẹni rere yóo sì jèrè ìwà rere rẹ̀.

15. Òpè eniyan a máa gba ohun gbogbo gbọ́,ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa kíyèsí ibi tí ó ń lọ.

16. Ọlọ́gbọ́n a máa ṣọ́ra, a sì máa sá fún ibi,ṣugbọn òmùgọ̀ kì í rọra ṣe, kì í sì í bìkítà.

17. Onínúfùfù a máa hùwà òmùgọ̀,ṣugbọn onílàákàyè a máa ní sùúrù.

18. Àwọn òpè a máa jogún àìgbọ́n,ṣugbọn àwọn ọlọ́gbọ́n a máa dé adé ìmọ̀.

19. Àwọn ẹni ibi yóo tẹríba fún àwọn ẹni rere,àwọn eniyan burúkú yóo sì tẹríba lẹ́nu ọ̀nà àwọn olódodo.

20. Àwọn aládùúgbò talaka pàápàá kórìíra rẹ̀,ṣugbọn ọlọ́rọ̀ a máa ní ọpọlọpọ ọ̀rẹ́.

21. Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀,ṣugbọn ayọ̀ ń bẹ fun ẹni tí ó bá ṣàánú talaka.

22. Àwọn tí wọn ń pète ibi ti ṣìnà,ṣugbọn àwọn tí wọn ń gbèrò ire yóo rí ojurere ati òtítọ́.

23. Kò sí iṣẹ́ kan tí kò lérè,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu lásán láìsí iṣẹ́, a máa sọ eniyan di aláìní.

24. Ọgbọ́n ni adé àwọn ọlọ́gbọ́n,ṣugbọn ìwà aláìgbọ́n jẹ́ yẹ̀yẹ́ àwọn òmùgọ̀.

25. Ẹlẹ́rìí tòótọ́ a máa gba ẹ̀mí là,ṣugbọn ọ̀dàlẹ̀ ni òpùrọ́.

26. Ninu ìbẹ̀rù OLUWA ni igbẹkẹle tí ó dájú wà,níbẹ̀ ni ààbò wà fún àwọn ọmọ ẹni.

27. Ìbẹ̀rù OLUWA ni orísun ìyè,òun níí mú ká yẹra fún tàkúté ikú.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 14