Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 14:10-19 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Kálukú ló mọ ìbànújẹ́ ọkàn ara rẹ̀,kò sì sí àjèjì tí ń báni pín ninu ayọ̀.

11. Ìdílé ẹni ibi yóo parun,ṣugbọn ilé olódodo yóo máa gbèrú títí lae.

12. Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí ẹni pé ó tọ́ lójú eniyan,ṣugbọn òpin rẹ̀, ikú ni.

13. Eniyan lè máa rẹ́rìn-ín, kí inú rẹ̀ má dùn,ìbànújẹ́ sì le gbẹ̀yìn ayọ̀.

14. Alágàbàgebè yóo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́,ẹni rere yóo sì jèrè ìwà rere rẹ̀.

15. Òpè eniyan a máa gba ohun gbogbo gbọ́,ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa kíyèsí ibi tí ó ń lọ.

16. Ọlọ́gbọ́n a máa ṣọ́ra, a sì máa sá fún ibi,ṣugbọn òmùgọ̀ kì í rọra ṣe, kì í sì í bìkítà.

17. Onínúfùfù a máa hùwà òmùgọ̀,ṣugbọn onílàákàyè a máa ní sùúrù.

18. Àwọn òpè a máa jogún àìgbọ́n,ṣugbọn àwọn ọlọ́gbọ́n a máa dé adé ìmọ̀.

19. Àwọn ẹni ibi yóo tẹríba fún àwọn ẹni rere,àwọn eniyan burúkú yóo sì tẹríba lẹ́nu ọ̀nà àwọn olódodo.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 14