Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 14:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọlọ́gbọ́n obinrin a máa kọ́ ilé rẹ̀,ṣugbọn òmùgọ̀ a máa fi ọwọ́ ara rẹ̀ tú tirẹ̀ palẹ̀.

2. Ẹni tí ń rìn pẹlu òótọ́ inú yóo bẹ̀rù OLUWA,ṣugbọn ẹni tí ń rin ìrìn ségesège yóo kẹ́gàn rẹ̀.

3. Ọ̀rọ̀ ẹnu òmùgọ̀ dàbí pàṣán ní ẹ̀yìn ara rẹ̀,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n a máa dáàbò bò ó.

4. Níbi tí kò bá sí mààlúù tí ń tu ilẹ̀, kò lè sí oúnjẹ,ṣugbọn agbára ọpọlọpọ mààlúù níí mú ọpọlọpọ ìkórè wá.

5. Ẹlẹ́rìí òtítọ́ kì í parọ́,ṣugbọn irọ́ ṣá ni ti ẹlẹ́rìí èké.

6. Pẹ̀gànpẹ̀gàn a máa wá ọgbọ́n, sibẹ kò ní rí i,ṣugbọn ati ní ìmọ̀ kò ṣòro fún ẹni tí ó ní òye.

7. Yẹra fún òmùgọ̀,nítorí o kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n lẹ́nu rẹ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 14