Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 13:9-25 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ìmọ́lẹ̀ olódodo a máa fi ayọ̀ tàn,ṣugbọn fìtílà eniyan burúkú yóo kú.

10. Ìjà ni ìgbéraga máa ń fà,ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá gba ìmọ̀ràn yóo ní ọgbọ́n.

11. Ọrọ̀ tí a fi ìkánjú kójọ kì í pẹ́ dínkù,ṣugbọn ẹni tí ó bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kó ọrọ̀ jọ yóo máa ní àníkún.

12. Bí ìrètí bá pẹ́ jù, a máa kó àárẹ̀ bá ọkàn,ṣugbọn kí á tètè rí ohun tí à ń fẹ́ a máa mú ara yá gágá.

13. Ẹni tí ó kẹ́gàn ìmọ̀ràn yóo parun,ṣugbọn ẹni tí ó bá bẹ̀rù òfin yóo jèrè rẹ̀.

14. Ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyèa máa yọni ninu tàkúté ikú.

15. Ẹni tí ó ní òye yóo rí ojurere,ṣugbọn ọ̀nà àwọn tí kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni ìparun wọn.

16. Olóye eniyan a máa fi ìmọ̀ ṣe ohun gbogbo,ṣugbọn òmùgọ̀ a máa fi agọ̀ rẹ̀ yangàn.

17. Iranṣẹ burúkú a máa kó àwọn eniyan sinu wahala,ṣugbọn ikọ̀ tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ a máa mú ìrẹ́pọ̀ wá.

18. Òṣì ati àbùkù ni yóo bá ẹni tí ó kọ ìmọ̀ràn,ṣugbọn ẹni tó bá gba ìbáwí yóo gba iyì.

19. Bí èrò ọkàn ẹni bá ṣẹ, a máa fúnni láyọ̀,ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ kórìíra ati kọ ibi sílẹ̀.

20. Bí eniyan bá ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóo gbọ́n,ṣugbọn ẹni tí ó bá ń bá òmùgọ̀ kẹ́gbẹ́ yóo ṣìnà.

21. Àjálù kì í dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,ṣugbọn olódodo yóo máa rí ire.

22. Eniyan rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀,ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń kó ọrọ̀ jọ fún àwọn olóòótọ́.

23. Oko tí talaka dá lè mú ọpọlọpọ oúnjẹ jáde,ṣugbọn àwọn alaiṣootọ níí kó gbogbo rẹ̀ lọ.

24. Ẹni tí kì í bá na ọmọ rẹ̀ kò fẹ́ràn rẹ̀,ṣugbọn ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóo máa bá a wí.

25. Olódodo a máa jẹ àjẹtẹ́rùn,ṣugbọn eniyan burúkú kì í yó.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 13