Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 13:2-13 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Eniyan rere a máa rí ire nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀,ṣugbọn ohun tí àwọn ẹlẹ́tàn ń fẹ́ ni ìwà jàgídíjàgan.

3. Ẹni tí ó ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó ń ṣọ́,ẹni tí ń sọ̀rọ̀ àsọjù yóo parun.

4. Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́ nǹkan, ṣugbọn kò ní rí i,ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ nǹkan.

5. Olóòótọ́ a máa kórìíra èké,ṣugbọn eniyan burúkú a máa hùwà ìtìjú ati àbùkù.

6. Òdodo a máa dáàbò bo ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́,ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ a máa bi eniyan burúkú ṣubú.

7. Ẹnìkan ń ṣe bí ọlọ́rọ̀,bẹ́ẹ̀ kò ní nǹkankan,níbẹ̀ ni ẹlòmíràn ń ṣe bíi talaka,ṣugbọn tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀.

8. Ọlọ́rọ̀ a máa fi ohun ìní rẹ̀ ra ẹ̀mí rẹ̀ pada,ṣugbọn talaka kì í tilẹ̀ gbọ́ ìbáwí.

9. Ìmọ́lẹ̀ olódodo a máa fi ayọ̀ tàn,ṣugbọn fìtílà eniyan burúkú yóo kú.

10. Ìjà ni ìgbéraga máa ń fà,ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá gba ìmọ̀ràn yóo ní ọgbọ́n.

11. Ọrọ̀ tí a fi ìkánjú kójọ kì í pẹ́ dínkù,ṣugbọn ẹni tí ó bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kó ọrọ̀ jọ yóo máa ní àníkún.

12. Bí ìrètí bá pẹ́ jù, a máa kó àárẹ̀ bá ọkàn,ṣugbọn kí á tètè rí ohun tí à ń fẹ́ a máa mú ara yá gágá.

13. Ẹni tí ó kẹ́gàn ìmọ̀ràn yóo parun,ṣugbọn ẹni tí ó bá bẹ̀rù òfin yóo jèrè rẹ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 13