Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 13:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀,ṣugbọn ẹlẹ́yà kì í gbọ́ ìbáwí.

2. Eniyan rere a máa rí ire nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀,ṣugbọn ohun tí àwọn ẹlẹ́tàn ń fẹ́ ni ìwà jàgídíjàgan.

3. Ẹni tí ó ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó ń ṣọ́,ẹni tí ń sọ̀rọ̀ àsọjù yóo parun.

4. Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́ nǹkan, ṣugbọn kò ní rí i,ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ nǹkan.

5. Olóòótọ́ a máa kórìíra èké,ṣugbọn eniyan burúkú a máa hùwà ìtìjú ati àbùkù.

6. Òdodo a máa dáàbò bo ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́,ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ a máa bi eniyan burúkú ṣubú.

7. Ẹnìkan ń ṣe bí ọlọ́rọ̀,bẹ́ẹ̀ kò ní nǹkankan,níbẹ̀ ni ẹlòmíràn ń ṣe bíi talaka,ṣugbọn tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀.

8. Ọlọ́rọ̀ a máa fi ohun ìní rẹ̀ ra ẹ̀mí rẹ̀ pada,ṣugbọn talaka kì í tilẹ̀ gbọ́ ìbáwí.

9. Ìmọ́lẹ̀ olódodo a máa fi ayọ̀ tàn,ṣugbọn fìtílà eniyan burúkú yóo kú.

10. Ìjà ni ìgbéraga máa ń fà,ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá gba ìmọ̀ràn yóo ní ọgbọ́n.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 13