Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 12:9-28 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Mẹ̀kúnnù tí ó ní iṣẹ́, tí ó tún gba ọmọ-ọ̀dọ̀ó sàn ju ẹni tí ó ń ṣe bí eniyan pataki, ṣugbọn tí kò rí oúnjẹ jẹ lọ.

10. Olódodo a máa ka ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn rẹ̀ sí,ṣugbọn eniyan burúkú rorò sí tirẹ̀.

11. Ẹni tí ó bá ń dáko yóo ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ,ṣugbọn ẹni tí ó bá ń lo àkókò rẹ̀ lórí ohun tí kò lérè, kò lọ́gbọ́n lórí.

12. Ilé ìṣọ́ àwọn eniyan burúkú yóo di òkítì àlàpà,ṣugbọn gbòǹgbò eniyan rere a máa fìdí múlẹ̀ sí i.

13. Ọ̀rọ̀ ẹnu eniyan burúkú a máa mú un bíi tàkúté,ṣugbọn olódodo a máa bọ́ ninu ìyọnu.

14. Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa mú ìtẹ́lọ́rùn bá a,a sì máa jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

15. Ọ̀nà òmùgọ̀ níí dára lójú tirẹ̀,ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa fetí sí ìmọ̀ràn.

16. Bí inú bá ń bí òmùgọ̀, kíá ni gbogbo eniyan yóo mọ̀,ṣugbọn ọlọ́gbọ́n kìí ka ọ̀rọ̀ àbùkù sí.

17. Ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ a máa jẹ́rìí òdodo,ṣugbọn irọ́ ni ẹlẹ́rìí èké máa ń pa.

18. Ẹni tí í bá máa ń sọ̀rọ̀ jàbùjàbù láìronú,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí kí á fi idà gún eniyan,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹni wo ọgbẹ́ sàn.

19. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ yóo máa wà títí ayéṣugbọn irọ́, fún ìgbà díẹ̀ ni.

20. Ẹ̀tàn ń bẹ lọ́kàn àwọn tí ń pète ibi,ṣugbọn àwọn tí ń gbèrò rere ní ayọ̀.

21. Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí olódodo,ṣugbọn eniyan burúkú yóo kún fún ìyọnu.

22. OLUWA kórìíra ẹni tí ń parọ́,ṣugbọn inú rẹ̀ dùn sí olóòótọ́.

23. Ọlọ́gbọ́n a máa fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́,ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa kéde agọ̀ wọn.

24. Ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ ni yóo máa jẹ́ olórí,ṣugbọn ọ̀lẹ ni a óo máa mú ṣiṣẹ́ tipátipá.

25. Ọ̀pọ̀ ìpayà máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá eniyan,ṣugbọn ọ̀rọ̀ rere a máa mú inú eniyan dùn.

26. Olódodo a máa yipada kúrò ninu ibi,ṣugbọn ìwà ẹni ibi a máa mú un ṣìnà.

27. Ọwọ́ ọ̀lẹ kò lè tẹ ohun tí ó ń lé,ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ ọrọ̀.

28. Ní ọ̀nà òdodo ni ìyè wà,kò sí ikú ní ojú ọ̀nà rẹ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 12