Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 12:2-21 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Eniyan rere a máa ní ojurere lọ́dọ̀ OLUWA,ṣugbọn ẹni tí ń pète ìkà ni yóo dá lẹ́bi.

3. Kò sí ẹni tí ó lè ti ipa ìwà ìkà fi ìdí múlẹ̀,ṣugbọn gbòǹgbò olódodo kò ní fà tu.

4. Obinrin oníwàrere ni adé orí ọkọ rẹ̀,ṣugbọn obinrin tí ń dójúti ọkọ dàbí ọyún inú egungun.

5. Èrò ọkàn olódodo dára,ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú.

6. Ọ̀rọ̀ àwọn eniyan burúkú dàbí ẹni tí ó lúgọ láti pa eniyan,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo a máa gbani là.

7. A bi àwọn eniyan burúkú lulẹ̀, wọ́n sì parun,ṣugbọn ìdílé olódodo yóo dúró gbọningbọnin.

8. À máa ń yin eniyan gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe gbọ́n tó,ṣugbọn ọlọ́kàn àgàbàgebè yóo di ẹni ẹ̀gàn.

9. Mẹ̀kúnnù tí ó ní iṣẹ́, tí ó tún gba ọmọ-ọ̀dọ̀ó sàn ju ẹni tí ó ń ṣe bí eniyan pataki, ṣugbọn tí kò rí oúnjẹ jẹ lọ.

10. Olódodo a máa ka ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn rẹ̀ sí,ṣugbọn eniyan burúkú rorò sí tirẹ̀.

11. Ẹni tí ó bá ń dáko yóo ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ,ṣugbọn ẹni tí ó bá ń lo àkókò rẹ̀ lórí ohun tí kò lérè, kò lọ́gbọ́n lórí.

12. Ilé ìṣọ́ àwọn eniyan burúkú yóo di òkítì àlàpà,ṣugbọn gbòǹgbò eniyan rere a máa fìdí múlẹ̀ sí i.

13. Ọ̀rọ̀ ẹnu eniyan burúkú a máa mú un bíi tàkúté,ṣugbọn olódodo a máa bọ́ ninu ìyọnu.

14. Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa mú ìtẹ́lọ́rùn bá a,a sì máa jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

15. Ọ̀nà òmùgọ̀ níí dára lójú tirẹ̀,ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa fetí sí ìmọ̀ràn.

16. Bí inú bá ń bí òmùgọ̀, kíá ni gbogbo eniyan yóo mọ̀,ṣugbọn ọlọ́gbọ́n kìí ka ọ̀rọ̀ àbùkù sí.

17. Ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ a máa jẹ́rìí òdodo,ṣugbọn irọ́ ni ẹlẹ́rìí èké máa ń pa.

18. Ẹni tí í bá máa ń sọ̀rọ̀ jàbùjàbù láìronú,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí kí á fi idà gún eniyan,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹni wo ọgbẹ́ sàn.

19. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ yóo máa wà títí ayéṣugbọn irọ́, fún ìgbà díẹ̀ ni.

20. Ẹ̀tàn ń bẹ lọ́kàn àwọn tí ń pète ibi,ṣugbọn àwọn tí ń gbèrò rere ní ayọ̀.

21. Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí olódodo,ṣugbọn eniyan burúkú yóo kún fún ìyọnu.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 12