Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 12:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹni tí ó fẹ́ ìtọ́sọ́nà, ó fẹ́ ìmọ̀,ṣugbọn ẹni tí ó kórìíra ìbáwí òmùgọ̀ ni.

2. Eniyan rere a máa ní ojurere lọ́dọ̀ OLUWA,ṣugbọn ẹni tí ń pète ìkà ni yóo dá lẹ́bi.

3. Kò sí ẹni tí ó lè ti ipa ìwà ìkà fi ìdí múlẹ̀,ṣugbọn gbòǹgbò olódodo kò ní fà tu.

4. Obinrin oníwàrere ni adé orí ọkọ rẹ̀,ṣugbọn obinrin tí ń dójúti ọkọ dàbí ọyún inú egungun.

5. Èrò ọkàn olódodo dára,ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú.

6. Ọ̀rọ̀ àwọn eniyan burúkú dàbí ẹni tí ó lúgọ láti pa eniyan,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo a máa gbani là.

7. A bi àwọn eniyan burúkú lulẹ̀, wọ́n sì parun,ṣugbọn ìdílé olódodo yóo dúró gbọningbọnin.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 12