Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 11:5-15 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Òdodo ẹni pípé a máa mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́,ṣugbọn ẹni ibi ṣubú nípa ìwà ìkà rẹ̀.

6. Ìwà òdodo àwọn olóòótọ́ yóo gbà wọ́n,ṣugbọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀dàlẹ̀ yóo dè wọ́n nígbèkùn.

7. Nígbà tí àwọn eniyan burúkú bá kú,ìrètí wọn yóo di asán,bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn tí kò mọ Ọlọrun yóo di òfo.

8. OLUWA a máa gba olódodo lọ́wọ́ ìyọnu,ṣugbọn ẹni ibi a bọ́ sinu wahala.

9. Ẹni tí kò mọ Ọlọrun a máafi ẹnu ba ti aládùúgbò rẹ̀ jẹ́,ṣugbọn nípa ìmọ̀ a máa gba olódodo sílẹ̀.

10. Nígbà tí nǹkan bá ń dára fún olódodo,gbogbo ará ìlú a máa yọ̀,nígbà tí eniyan burúkú bá kú,gbogbo ará ìlú a sì hó ìhó ayọ̀.

11. Ìre tí olódodo bá sú fún ìlú a máa gbé orúkọ ìlú ga,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn eniyan burúkú a máa run ìlú.

12. Ẹni tí ó tẹmbẹlu aládùúgbò rẹ̀ kò gbọ́n,ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa pa ẹnu mọ́.

13. Olófòófó a máa tú àṣírí,ṣugbọn ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a máa pa àṣírí mọ́.

14. Níbi tí kò bá ti sí ìtọ́ni, orílẹ̀-èdè a máa ṣubú,ṣugbọn ẹni tí ó bá ní ọpọlọpọ olùdámọ̀ràn yóo máa gbé ní àìléwu.

15. Ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò yóo rí ìyọnu,ṣugbọn ẹni tí ó bá kọ̀ tí kò ṣe onídùúró yóo wà láìléwu.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 11