Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 11:21-31 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Dájúdájú ẹni ibi kò ní lọ láìjìyà,ṣugbọn a óo gba àwọn olódodo là.

22. Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀ni obinrin tí ó lẹ́wà tí kò ní làákàyè.

23. Ìfẹ́ ọkàn olódodo a máa yọrí sí rere,ṣugbọn ìrètí eniyan burúkú a máa já sí ibinu.

24. Ẹnìkan wà tíí máa ṣe ìtọrẹ àánú káàkiri,sibẹsibẹ àníkún ni ó ń ní,ẹnìkan sì wà tí ó háwọ́,sibẹsibẹ aláìní ni.

25. Ẹni tí ó bá lawọ́ yóo máa ní àníkún,ẹni tí ó bá jẹ́ kí ọkàn ẹlòmíràn balẹ̀,ọkàn tirẹ̀ náà yóo balẹ̀.

26. Ẹni tí ó bá ń kó oúnjẹ pamọ́, yóo gba ègún sórí,ṣugbọn ẹni tí ó bá ń ta oúnjẹ, yóo rí ibukun gbà.

27. Ẹni tí ó bá ń wá ire, yóo rí ojurere,ṣugbọn ẹni tí ó bá ń wá ibi, ibi yóo bá a.

28. Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóo rẹ̀ dànù bí òdòdó,ṣugbọn olódodo yóo rú bí ewé tútù.

29. Ẹni tí ó bá mú ìyọnu dé bá ìdílé rẹ̀ yóo jogún òfo,òmùgọ̀ ni yóo sì máa ṣe iranṣẹ ọlọ́gbọ́n.

30. Èso olódodo ni igi ìyè,ṣugbọn ìwà aibikita fún òfin a máa paniyan.

31. Bí a óo bá san ẹ̀san fún olódodo láyé,mélòó-mélòó ni ti eniyan burúkú ati ẹlẹ́ṣẹ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 11