Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 11:12-21 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Ẹni tí ó tẹmbẹlu aládùúgbò rẹ̀ kò gbọ́n,ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa pa ẹnu mọ́.

13. Olófòófó a máa tú àṣírí,ṣugbọn ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a máa pa àṣírí mọ́.

14. Níbi tí kò bá ti sí ìtọ́ni, orílẹ̀-èdè a máa ṣubú,ṣugbọn ẹni tí ó bá ní ọpọlọpọ olùdámọ̀ràn yóo máa gbé ní àìléwu.

15. Ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò yóo rí ìyọnu,ṣugbọn ẹni tí ó bá kọ̀ tí kò ṣe onídùúró yóo wà láìléwu.

16. Obinrin onínúrere gbayì,ṣugbọn ọrọ̀ nìkan ni ìkà yóo ní.

17. Ẹni tí ó ṣoore ṣe é fún ara rẹ̀,ẹni tí ó sì ń ṣìkà ó ń ṣe é fún ara rẹ̀.

18. Owó ọ̀yà èké ni eniyan burúkú óo gbà,ṣugbọn ẹni tí ó bá hùwà òdodo yóo gba èrè òtítọ́.

19. Ẹni tí ó dúró ṣinṣin lórí òdodo yóo yè,ṣugbọn ẹni tí ó bá ń lépa ibi yóo kú.

20. Ẹni ìríra ni àwọn alágàbàgebè lójú OLUWA,ṣugbọn àwọn tí ọ̀nà wọn mọ́ ni ìdùnnú fún un.

21. Dájúdájú ẹni ibi kò ní lọ láìjìyà,ṣugbọn a óo gba àwọn olódodo là.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 11