Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 10:25-32 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Nígbà tí ìjì líle bá ń jà, a gbá ẹni ibi lọ,ṣugbọn olódodo a fẹsẹ̀ múlẹ̀ títí lae.

26. Bí ọtí kíkan ti rí sí eyín,ati bí èéfín ti rí sí ojú,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ rí sí ẹni tí ó bẹ̀ ẹ́ níṣẹ́.

27. Ìbẹ̀rù OLUWA a máa mú kí ẹ̀mí eniyan gùn,ṣugbọn ìgbé ayé eniyan burúkú yóo kúrú.

28. Ìrètí olódodo yóo yọrí sí ayọ̀,ṣugbọn ìrètí ẹni ibi yóo jásí òfo.

29. OLUWA jẹ́ agbára fún àwọn tí ọ̀nà wọn tọ́,ṣugbọn ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ibi.

30. Gbọningbọnin ni olódodo yóo dúró,ṣugbọn ẹni ibi kò ní lè gbé ilẹ̀ náà.

31. Ẹnu olódodo kún fún ọ̀rọ̀ ọgbọ́n,ṣugbọn ẹnu alaiṣootọ ni a pamọ́.

32. Olódodo mọ ohun tí ó dára láti sọ,ṣugbọn ti eniyan burúkú kò ju ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn lọ.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 10