Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 1:29-33 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Nítorí pé ẹ kórìíra ìmọ̀,ẹ kò sì bẹ̀rù OLUWA.

30. Ẹ kò fẹ́ ìmọ̀ràn mi,ẹ sì kẹ́gàn gbogbo ìbáwí mi.

31. Nítorí náà, ẹ óo jèrè iṣẹ́ yín,ìwà burúkú yín yóo sì di àìsàn si yín lára.

32. Àwọn aláìgbọ́n kú nítorí pé wọn kò gba ẹ̀kọ́aibikita àwọn òmùgọ̀ ni yóo pa wọ́n run.

33. Ṣugbọn ẹni tí ó gbọ́ tèmi,yóo máa wà láìléwu,yóo máa gbé pẹlu ìrọ̀rùn, láìsí ìpayà ibi.”

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 1