Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 1:23-29 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Ẹ fetí sí ìbáwí mi,n óo ṣí ọkàn mi payá fun yín,n óo sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi ye yín.

24. Nítorí pé mo ti ké títí, kò sì sí ẹni tí ó gbọ́,mo ti na ọwọ́ si yín ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dá mi lóhùn,

25. ẹ ti pa gbogbo ìmọ̀ràn mi tì,ẹ kò sì gbọ́ ọ̀kankan ninu ìbáwí mi.

26. Èmi náà óo sì máa fi yín rẹ́rìn-ínnígbà tí ìdààmú bá dé ba yín,n óo máa fi yín ṣe ẹlẹ́yànígbà tí ìpayà bá dé ba yín.

27. Nígbà tí ìpayà bá dé ba yín bí ìjì,tí ìdààmú dé ba yín bí ìjì líle,tí ìpọ́njú ati ìrora bò yín mọ́lẹ̀.

28. Ẹ óo ké pè mí nígbà náà,ṣugbọn n kò ní dáhùn.Ẹ óo wá mi láìsinmi,ṣugbọn ẹ kò ní rí mi.

29. Nítorí pé ẹ kórìíra ìmọ̀,ẹ kò sì bẹ̀rù OLUWA.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 1