Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 1:12-22 BIBELI MIMỌ (BM)

12. jẹ́ kí á gbé wọn mì láàyèkí á gbé wọn mì lódidi bí isà òkú,

13. a óo rí àwọn nǹkan olówó iyebíye kó,ilé wa yóo sì kún fún ìkógun.

14. Ìwọ ṣá darapọ̀ mọ́ wa,kí á sì jọ lẹ̀dí àpò pọ̀.”

15. Ọmọ mi, má bá wọn kẹ́gbẹ́,má sì bá wọn rìn,

16. nítorí ọ̀nà ibi ni ẹsẹ̀ wọn máa ń yá sí,wọ́n a sì máa yára láti paniyan.

17. Asán ni àwọ̀n tí eniyan dẹ sílẹ̀,nígbà tí ẹyẹ tí a dẹ ẹ́ fún ń woni,

18. ṣugbọn ẹ̀jẹ̀ ara wọn ni irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ lúgọ dè,ìparun ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n lúgọ tí wọn ń retí.

19. Bẹ́ẹ̀ ni ti àwọn tí wọ́n ń fi ipá kó ọrọ̀ jọ rí,ọrọ̀ tí wọn fi ipá kójọ níí gba ẹ̀mí wọn.

20. Ọgbọ́n ń kígbe ní òpópónà,ó ń pariwo láàrin ọjà,

21. ó ń kígbe lórí odi ìlú,ó ń sọ̀rọ̀ ní àwọn ẹnubodè ìlú, ó ní,

22. “Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ óo ti pẹ́ tó ninu àìmọ̀kan yín?Àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn yóo ti ní inú dídùn pẹ́ tó ninu ẹ̀gàn pípa wọn,tí àwọn òmùgọ̀ yóo sì kórìíra ìmọ̀?

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 1