Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 1:11-27 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Bí wọn bá wí pé,“Tẹ̀lé wa ká lọ,kí á lọ sápamọ́ láti paniyan,kí á lúgọ de aláìṣẹ̀,

12. jẹ́ kí á gbé wọn mì láàyèkí á gbé wọn mì lódidi bí isà òkú,

13. a óo rí àwọn nǹkan olówó iyebíye kó,ilé wa yóo sì kún fún ìkógun.

14. Ìwọ ṣá darapọ̀ mọ́ wa,kí á sì jọ lẹ̀dí àpò pọ̀.”

15. Ọmọ mi, má bá wọn kẹ́gbẹ́,má sì bá wọn rìn,

16. nítorí ọ̀nà ibi ni ẹsẹ̀ wọn máa ń yá sí,wọ́n a sì máa yára láti paniyan.

17. Asán ni àwọ̀n tí eniyan dẹ sílẹ̀,nígbà tí ẹyẹ tí a dẹ ẹ́ fún ń woni,

18. ṣugbọn ẹ̀jẹ̀ ara wọn ni irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ lúgọ dè,ìparun ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n lúgọ tí wọn ń retí.

19. Bẹ́ẹ̀ ni ti àwọn tí wọ́n ń fi ipá kó ọrọ̀ jọ rí,ọrọ̀ tí wọn fi ipá kójọ níí gba ẹ̀mí wọn.

20. Ọgbọ́n ń kígbe ní òpópónà,ó ń pariwo láàrin ọjà,

21. ó ń kígbe lórí odi ìlú,ó ń sọ̀rọ̀ ní àwọn ẹnubodè ìlú, ó ní,

22. “Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ óo ti pẹ́ tó ninu àìmọ̀kan yín?Àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn yóo ti ní inú dídùn pẹ́ tó ninu ẹ̀gàn pípa wọn,tí àwọn òmùgọ̀ yóo sì kórìíra ìmọ̀?

23. Ẹ fetí sí ìbáwí mi,n óo ṣí ọkàn mi payá fun yín,n óo sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi ye yín.

24. Nítorí pé mo ti ké títí, kò sì sí ẹni tí ó gbọ́,mo ti na ọwọ́ si yín ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dá mi lóhùn,

25. ẹ ti pa gbogbo ìmọ̀ràn mi tì,ẹ kò sì gbọ́ ọ̀kankan ninu ìbáwí mi.

26. Èmi náà óo sì máa fi yín rẹ́rìn-ínnígbà tí ìdààmú bá dé ba yín,n óo máa fi yín ṣe ẹlẹ́yànígbà tí ìpayà bá dé ba yín.

27. Nígbà tí ìpayà bá dé ba yín bí ìjì,tí ìdààmú dé ba yín bí ìjì líle,tí ìpọ́njú ati ìrora bò yín mọ́lẹ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 1