Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Oníwàásù 7:18-29 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Di ekinni mú ṣinṣin, má sì jẹ́ kí ekeji bọ́ lọ́wọ́ rẹ; nítorí ẹni tí ó bá bẹ̀rù Ọlọrun yóo ní ìlọsíwájú.

19. Ọgbọ́n yóo mú ọlọ́gbọ́n lágbára ju ọba mẹ́wàá lọ láàrin ìlú.

20. Kò sí olódodo kan láyé tí ń ṣe rere, tí kò lẹ́ṣẹ̀.

21. Má máa fetí sí gbogbo nǹkan tí àwọn eniyan bá wí, kí o má baà gbọ́ pé iranṣẹ rẹ kan ń bú ọ.

22. Ìwọ náà mọ̀ ní ọkàn rẹ pé, ní ọpọlọpọ ìgbà ni ìwọ náà ti bú eniyan rí.

23. Gbogbo nǹkan wọnyi ni mo ti fi ọgbọ́n wádìí. Mo sọ ninu ara mi pé, “Mo fẹ́ gbọ́n,” ṣugbọn ọgbọ́n jìnnà sí mi.

24. Ta ló lè ṣe àwárí ohun tó jìnnà gbáà, tí ó jinlẹ̀ gan-an?

25. Mo tún pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́, láti ṣe ìwádìí, ati láti wá ọgbọ́n, kí n mọ gbogbo nǹkan, ati ibi tí ń bẹ ninu ìwà òmùgọ̀, ati àìlóye tí ó wà ninu ìwà wèrè.

26. Mo rí i pé, nǹkankan wà tí ó burú ju ikú lọ: òun ni obinrin oníṣekúṣe. Ọkàn rẹ̀ dàbí tàkúté ati àwọ̀n, tí ọwọ́ rẹ̀ dàbí ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀. Ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọrun kò ní bọ́ sọ́wọ́ rẹ̀, ṣugbọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo kó sinu tàkúté rẹ̀.

27. Ohun tí mo rí nìyí, lẹ́yìn tí mo farabalẹ̀ ṣe ìwádìí pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́,

28. òun ni mò ń rò nígbà gbogbo, sibẹ, ó ṣì ń rú mi lójú: Láàrin ẹgbẹrun ọkunrin a lè rí ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ́ eniyan rere, ṣugbọn ninu gbogbo àwọn obinrin, kò sí ẹnìkan.

29. Ẹ̀kọ́ tí mo rí kọ́ ni pé rere ni Ọlọrun dá eniyan, ṣugbọn àwọn ni wọ́n wá oríṣìíríṣìí ọ̀nà àrékérekè fún ara wọn.

Ka pipe ipin Ìwé Oníwàásù 7