Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Oníwàásù 4:10-16 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Bí ọ̀kan bá ṣubú,ekeji yóo gbé e dìde.Ṣugbọn ẹni tí ó dá wà gbé!Nítorí nígbà tí ó bá ṣubúkò ní sí ẹni tí yóo gbé e dìde.

11. Bẹ́ẹ̀ sì tún ni, bí eniyan meji bá sùn pọ̀,wọn yóo fi ooru mú ara wọnṣugbọn báwo ni ẹnìkan ṣe lè fi ooru mú ara rẹ̀?

12. Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ni eniyan kan lè dojú ìjà kọ,nítorí pé eniyan meji lè gba ara wọn kalẹ̀.Okùn onípọn mẹta kò lè ṣe é já bọ̀rọ̀.

13. Ọlọ́gbọ́n ọdọmọde tí ó jẹ́ talaka, sàn ju òmùgọ̀ àgbàlagbà ọba, tí kò jẹ́ gba ìmọ̀ràn lọ,

14. kì báà jẹ́ pé láti ọgbà ẹ̀wọ̀n ni òmùgọ̀ ọba náà ti bọ́ sórí ìtẹ́, tabi pé láti inú ìran talaka ni a ti bí i.

15. Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn kiri láyé ati ọdọmọde náà tí yóo gba ipò ọba.

16. Àwọn eniyan tí ó jọba lé lórí pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní òǹkà; sibẹ, àwọn ìran tí ó bá dé lẹ́yìn kò ní máa yọ̀ nítorí rẹ̀. Dájúdájú asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí.

Ka pipe ipin Ìwé Oníwàásù 4